Ijamba ọkọ gbẹmi eeyan mọkandinlogun ni Kwara

Ijamba ọkọ gbẹmi eeyan mọkandinlogun ni Kwara
Ijamba ọkọ gbẹmi eeyan mọkandinlogun ni Kwara

Awon Ọmọ wewe marun-un ati agba mẹrinla, ni wọn ku ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, loju ọna maroṣẹ Kàńbí-Olóoru, nijọba ibilẹ Móòrò, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe mọto meji; tirela Iveco alawọ buluu ati ọkọ akero Toyota Hiace ni wọn kọ lu ara wọn. Lẹyin ti ọkan ninu wọn sare asapajude, to si n gbiyanju lati ya ẹnikeji silẹ lọna aitọ ni wọn kagbako ijamba naa.

Alukoro ileeṣẹ ẹṣọ oju popo ni Kwara, Oluṣẹgun Ogungbemide, ṣalaye pe ṣe ni awọn mọto mejeeji fẹẹ ya ara wọn silẹ lọna aitọ (wrongful overtaking) ti wahala naa fi ṣẹlẹ ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii.

O ni eeyan mọkandinlogun lo ku loju-ẹsẹ, ninu eyi ti mọkanla ninu wọn jẹ ọkunrin ati obinrin mẹta, awọn ọmọ kekere marun-un, ọkunrin mẹta, obinrin meji ni wọn ku, nigba ti awọn marun-un kan fara pa ninu ijamba ọhun, ti wọn si ti n gba itọju nileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Orísun Ayọ, lagbegbe naa.

Ogungbemi ṣalaye pe wọn ti gbe oku eeyan kan ninu awọn mọkandinlogun ọhun lọ sile igbokuu-si ti ileewosan yii kan naa, ti mọlẹbi awọn mejidinlogun yooku si ti waa gbe oku wọn.

O waa rọ awọn awakọ lati mọ pe ẹmi ko laarọ, ki wọn wakọ pẹlu suuru lasiko ọdun Ileya yii.

Adari agba fun ọjọ naa nilẹ yii, Shehu Mohammed, ti fi aidun rẹ han lori iṣẹlẹ naa.

O ni iṣẹlẹ buruku yii waye latari pe awọn awakọ to tẹle ofin irinna ti ajọ naa gbe kalẹ.


Be the first to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published.